Oludije fun ipo aare labe asia egbe oselu
Nationalist lorile-ede Taiwan, Ma Ying- jeou ti jawee olubori
pelu idije ibo ti won di lojo abameta (Saturday).
Egbe oselu alatako naa sope, ogbeni Ma, ti jawee
olubori pelu ibo ti iye re le ni milionu meje,eyi ti o koja
idaji milionnu metala eniyan.
Ajo eleto idibo sope, ogbeni Ma ti ni ibo iko
mejidinlogota nigbati egbe oselu Democratic Progressive Party ti
o n sejoba lowo ti oludije re Frank Hsiah ni ibo iko
mejidinlaadota ni eyi ti kika ibo si n tesiwaju.
Ogbeni Ma ni ajosepo eto oro aje ati eto ijiroro
oloselu pelu orile-ede China, eyi ti o sope, o je adase ijoba
orile-ede Taiwan gege bi ti ara-re, ni eyi ti ko si fi igba kan
lo ipa lati se akoso erekusu naa.