E se ayewo Ikanni yii
 

IKANSI AKANKAN

È KÀÁBÒ SÍ ORÍ ÈTÒ WÁ ......... ÈKÀ ÈDÈ YORÙBÁ ....

 

Awon alaase ni orile-ede Tibet ti fowo – sinkun mu awon eniyan merinlelogun kan (24), ti won fura-si lori esun – iwa – odaran, leyin ti awon omo ogun gbogun ti iwode awon ti won fehonu-won-han lati lodi si ijoba orile-ede China, eyi ti won fi takoigbaradi idije – ere- idaraya Olympic ti yoo waye nilu Beijing.

Ile-ise eleto-aabo kan, ti o wa niluu Lhasa ti n se olu-ilu orile-ede naa, se lalaye pe, awon ti fowo – sinkun- mu  awon eniyan ti won fura-si naa, fun idunkoko-moni lori eto-aabo, sise awon eniyan ni jamba ninu ifehonuha onijagidijagan naa ti o waye ni ojo – eti (Friday).

Ayeye idije ere- Olympic  ti ere-sisa(relay) ti yoo saaju idije na kakiri awon orile-ede mokandinlogun, eyi ti yoo bere lose-to-n-bo, ni o se-e-se ki o ma waye no orile-ede Tibet latari rogbodiyan awon afehonuhan.

Olori ijoba orile-ede Poland, Donald Tusk sope, bi nkan ko-ba-yipada, ose-se ki ijoba oun se iye-meji lati fi iko ranse sibi ayeye naa.

Oludije fun ipo Aare ni orile-ede Amerika ti ro orile-ede Amerika lati ja fun eto omoeniyan ni orile-ede Tibet, leyin ikolu oun.  Ijoba Aare Bush ati iko ajo isokan Europe ti ro orile-ede China lati wa ojutu si oro naa.

 

 

Home | Contact | VON | Contact Us | archive
Webmaster@voiceofnigeria.org :Change Password :VON Staff Sign Up
Copyright© 2007. All Rights Reserved Voice Of Nigeria. Developed by: VON ON-LINE

7255KHz 41m; 9690KHz 31m; 11770KHz 25m; 15120KHz  19m