Olori
orile-ede Tibet Dalai Lama, ti se lalaye pe, oun yoo kowe
fise-sile gege bi olori orile-ede naa ti nkan ko ba fara-ro ni
orile-ede naa.
Bakan naa,
o se kanle lori awon esun ti orile-ede China fi kan pe o-n-da
rogbodiyn sile .
Olori
ijoba orile-ede China, Wen- Jiabao ti fesun kan Dalai Lam wipe,
o n se agbateru rogbodiyan ni ilu Lhasa ti o je ilu kan gboogi
ni orile-ede Tibet.
Nigba ti o
n soro ni ipari ijoko ile – igbimo asofin, Ogbeni Wen tun see
lalaye pe, awon esun iapniyan lopo yanturu ti olori orile-ede
Tibet ti o fara sinko n fi-kan, je iro pata-pata.
Awon olori
orile-ede Tibet ti won n fi ara-sinko so pe, o kerer-tan ogorin
awon afehonu-han ni won seku-pa ninu ikolu ti awon omo ogun
alaabo orile-ede China se.