Ile igbimo
asofin tuntun ni orile ede Pakistan ti se ipade akoko, leyin
igba ti aare Pervez Musharaff ati awon emewa-re ti forisopan
ninu eto idibo to koja, eyi ti o fa gbonmi – si – omi –o – to
larin ipade ijoba na ati Aare ohun.
Awon egbe
oselu olori ijoba ana ti won pa ni ipakupa, arabinrin Benazir
Bhuto ati egbe oselu olori ijoba Ana miiran, ogbeni Nawaz
sheriff ti fenu adehun – ko lati di okan. O le ni oodunrun awon
omo ile igbimo asofin naa ti won bura fun.
Egbe oselu
People Pakistan Party PPP, ti ologbe Bhuto ni ireti w ape yoo fa
olori ijoba sile, niwon ti o je awon ni o ni ijoko ti o poju
ninu ile igbimo asofin naa.