Aare Umaru Yara’Adua ti ro awon omo orile-ede
Naijiiria lati ri odun Ed-el-maluud ati odun Ajinde ti o sunmo-
ara-won ni odun yii gege bi ami pe ibasepo to – nipon wa laarin
esin Islam ati esin omoleyin Kristi.
Ipe aare Yar’Adua yii wa ninu ise ti o ran si
awon omo orile-ede Naijiiria ninu ayeye odun Ed-el-moluud ati
odun Ajinde. O salaye pe niwon igba ti o je pe opo awon omo
orile-ede Naijiiria ni won n se awon esin mejeeji yii, yoo se
orile-ede yii lanfaani bi won ba tele liana awon esin naa.
O menuba awon liana naa ti o je iwa omoluwabi,
bii ifi-ara-eniji,aimo-tara-eninikan,otito ifarada ati ife tooto
gegebi awon apeere ti ojise nla Muhammed ati jesu Kristi fi
leele.