E se ayewo Ikanni yii
 

IKANSI AKANKAN

È KÀÁBÒ SÍ ORÍ ÈTÒ WÁ ......... ÈKÀ ÈDÈ YORÙBÁ ....

 

Alaga igbimo teekoto ti o n ri si oro won obinrin ni ile igbimo Asofin ni orile-ede Naijiiria, Aarbirin Beni Lar ti pe fun sise agbekale iko kan ti yoo ma daabo-bo awon omode ni orile-ede way ii.

Aarbinrin Bani Lar soro yii ni ilu Abuja ti I se olu-ilu orile-ede Naijiiria wi pe iru iko bee yoo le tete mojuto ofin ti o fi eto awon omode mule, eyi ti ile igbimo Asofin ti fowo sii.

O te siwaju pe iko naa yoo le samoju iwakuwa, eyi ti awon eniyan ti n lo omode ni ilo-kuulo.

Asofin naa woye wipe bi-o-ti-le- je wipe ile-igbio Asofin ti fowo sii ofin naa lojo to tipe, sibe iwa lilo omode ni ilo-kulo yii si n pe ni nitori aisi iko ti yoo maa mojuto ofin yii.

O tun te siwaju pe, opo ipinle naa ni ko fi oro okunkundun mu ofin naa, o fi kun oro re wipe, ipinle mejila pere ninu ipinle orile-ede yii ni won fowo si ofin naa bayii.

 

 

Home | Contact | VON | Contact Us | archive
Webmaster@voiceofnigeria.org :Change Password :VON Staff Sign Up
Copyright© 2007. All Rights Reserved Voice Of Nigeria. Developed by: VON ON-LINE

7255KHz 41m; 9690KHz 31m; 11770KHz 25m; 15120KHz  19m