E se ayewo Ikanni yii
 

IKANSI AKANKAN

È KÀÁBÒ SÍ ORÍ ÈTÒ WÁ ......... ÈKÀ ÈDÈ YORÙBÁ ....

 

Ijoba orile-ede Naijiiria ti sagbekale igbimo – teekoto ti yoo moju to iseto ati kopa orile-ede ti o n wa-epo robi lagbaue, eyi ti won pe ni World Petroleum Congress (WPC) eyi ti yoo waye ni ilu Maldrib ni orile-ede Spain.

Alaga igbimo teeekoto naa, eni ti o je oga agba fun eka alukoro Ajo ti o n mojuto epo- robi lorile-ede Naijiiria National Petroleum Coporation (NPC) omowe Levi Ajuonuwa ni o so oro yii di mimo nigba ti o wa ni apa iwo-oorun Guusu orile-ede Naijiiria.

Akori ipade apero odun yii ni Ayipada ti o ti de-ba agbaye nipa lilo ohun amusagbara fun fifi igberu mule, ti won n pe ni “A world in Transition” Delivering Energy for Sustanable ninu eyi ti won yoo ti sagbeyewo bi iye eniyan se n po-si lagbaye ati oan ohun amusagbarafun igberu ati isokan agbaye.

Omowe Ajuonuma fi kun oro – re pe, orile-ede Naijiiria gege bi okan lara awon orile-ede ti o n pese epo-robi julo lagbaye  ti o ni anfaani lati maa pese epo-robi deede lalai fi owo-re ni awon eniyan lara.

O se lalaye pe, iru ipade apero yii yoo fun orile-ede Naijiiria laatari lati je ki awon orile-ede ti won n pese epo- robi lagbaye mo nipa erongbaonikoko meje Aare Yar’Adua, pelu erongba  ati fifa awon olookowo mora si inu owo(trade) epo-robi ati afefe-gaasi orile-ede Naijiiria.

Ipade apero WPC naa, elekokandinlogun iru-re, eyi ti o n waye leekan laarin odun merin ni yoo waye ni aarin ojo kokandinlogun osu kefa sii ojo keta osu keje odun yii ni orile-ede Spain.

 

Home | Contact | VON | Contact Us | archive
Webmaster@voiceofnigeria.org :Change Password :VON Staff Sign Up
Copyright© 2007. All Rights Reserved Voice Of Nigeria. Developed by: VON ON-LINE

7255KHz 41m; 9690KHz 31m; 11770KHz 25m; 15120KHz  19m