Loni ni
odun ti a mo si Eil-el-Maalude, ojo kan ti awon musulumi n saami
iranti ojo ibi anobi Muhammed, ki ike ati ola olorun ki o maa be
fun un.
Won maa n
saami ayeye naa pelu kika Al-Qurian ati awon iwe miiran ti o je
mo esun Islam ni gbogbo oru ati ojo naa ti o je ojo kejila ninu
osu Rubiul Awwal ti o je osu keta ninu osu oju orun awon elesin
misulumi.
Lemomu
Fuad Adeyemi ti mosalasi Al-Habibiyah ti o wa ni Wusa niluu
Abuja ti o je olu-ilu orile-ede Naijiiria baa won eniyan soro
nipa Pataki ojo naa, ti o si tun ro awon ijo musulumi lati wo
awokose ise Anobi Muhammed (SWA) ninu gbogbo ohun ti won ba n
gbe se.
Won maa n
se odun ojo ibi Anobi Muhammed pelu olokan-o-jokan ere idaraya
ati sise paasipaaro ebun ni awon apa kan lorile-ede Naijiiria.