E se ayewo Ikanni yii
 

IKANSI AKANKAN

È KÀÁBÒ SÍ ORÍ ÈTÒ WÁ ......... ÈKÀ ÈDÈ YORÙBÁ ....

 

 

Ile igbimo asofin ni orile ede amerika ti gboriyin fun ise takun-takun ti ajo to n gbogun ti iwa ibaje lorile-ede Naijiiria, eyi ti a mo sii(Economic and Fanancial Crime Commission) EFCC n se.

Nigba ti o n soro lasiko abewo kan sii ile – ise ajo naa to wa ni ilu Abuja, okan lara awon omo ile igbimo naa so pea won nife si nnkan ti ajo naa n se, ni eyi ti won fi idunnu won han lati sise pelu ajo naa lati gbogun ti iwa ibaje.

Ogbeni Ibrahim Lamorde ti o je adele alaga ajo naa, eni ti o dari awon osise agba ile-ise naa lati gba awon asofin naa lalejo salaye wipe, ijoba apapo lo se agbekale ajo naa latari ona ati fie dun okan won han, bi awon eniyan se n ko owo ara-ilu lo si ile-okere ati dekun awon iwa ibaje lawujo. O se lalaye pe, idasile ile-ise agbofinro ni orile-ede Naijiiria wa lati dekun orisirisi iwa ibaje to n gbinle lawujo.

O fid a awon asofin naa loju pe, ajo EFCC da duro lati gbogun ti iwa ibaje lawujo.  O tenumo wipe, ajo naa ni ase lati fi owo-sinkun-mu ati lati baa won odaran naa rojo.

 

Ajo orile-ede Naijiiria ati orile-ede Cameroon ti fenu-ko lori pinpin ile ati eti’kun  ibode ti o wa laarin orile-ede mejeji fun awon agbase-se.

Eyi yoo je ipele keerin pinpin akanse ise naa bayii, ti ajo ohun ti gbe jade.

Adari asoju orile-ede Naijiiria si ajo naaomo oba Bola Ajibola so ni ilu Younde ni orile-ede Cameroon pe, osunwon erongba ajo naa ni lati pari ise naa ni kope-kojina.

O salaye pe, pelu gbigbe akanse ise mejeeji yii jade, o ku ise kan pere ti ajo ohun ni lati gbe jade.

Orile ede Naijiiria ati orle-ede Cameroon ti fenu-ko lati lo awon akose-mose won lati pin awon agbegbe kan ti o wa ni apa ariwa nibi ti awon opo kan wa tele lati se adinku asiko ati owo.

 

Home | Contact | VON | Contact Us | archive
Webmaster@voiceofnigeria.org :Change Password :VON Staff Sign Up
Copyright© 2007. All Rights Reserved Voice Of Nigeria. Developed by: VON ON-LINE

7255KHz 41m; 9690KHz 31m; 11770KHz 25m; 15120KHz  19m