E se ayewo Ikanni yii
 

IKANSI AKANKAN

È KÀÁBÒ SÍ ORÍ ÈTÒ WÁ ......... ÈKÀ ÈDÈ YORÙBÁ ....

 

Bi iteti si ti bere lorile ede Naijiiria lori owo ti won na ni eka agbara, won ti pe gomina ipinle Cross river, asofin Liyal Imoke lati fojuhan niwaju awon igbimo asewadii.

Asofin Imoke n dahun awon ibere ti won je mo ise agbase bilionnu mejidinlaadorun dola ti won gbe fun ile ise kan ti a mo si Rockson Nigeria Limited ti o je ti asofin Anietie Okon.

Won sun esun pe, ise agbase naa ko tele ona ti o ye.  Bakan  naa ni giwa ile ifowopamo apaapo lorile ede Najiiria, CBN, ojogbon Chukwuna Soludo yoo fojuhan niwaju igbimo naa. 

Atileyn ti wa fun idajo lori iwa apileko ipenija idibo gomina ipinle Oyo ti o wa ni iha iwo oorun guusu orile ede Naijiiria, otunba Adebayo Alao Akala.

Bi o tile je pe meta ninu awon igbimo adajo ti won wa nidii ejo naa se atileyin fun idibo naa, okan ninu won beere fun fifagile eto idibo latari pea won kan ko ni anfaani lati dibo.

Oludije fun ipo gomina labe asia egbe oselu ANPP, asofin Abiola Ajimobi ti pawopo pelu awon egbe oselu maarun miiran fun ipenija jijawee olubori gomina Alao Akala nibi eto idibo ti o waye ninu osu kerin odun ti o koja.

Awon ti won kowe ifeyin-ti naa, so pe igbimo asewadii kan ti gomina ana Rashid Ladoja se agbekalere ti fi esun kan gomina Alao Akala nitori idi eyi ko poju-osuwan lati dije fun ipo gomina.

 

 

Home | Contact | VON | Contact Us | archive
Webmaster@voiceofnigeria.org :Change Password :VON Staff Sign Up
Copyright© 2007. All Rights Reserved Voice Of Nigeria. Developed by: VON ON-LINE

7255KHz 41m; 9690KHz 31m; 11770KHz 25m; 15120KHz  19m