Aare Robert Mugabe ti orile-ede Zimbabwe ti kilo
fun awon egbe oselu alatako lati yago fun rogbodiyan, iru eyi ti
o waye ni orile-ede Kenya, ti won ba fidi-remi ninu eto idibo ti
yoo waye ninu ose to-n-bo, O tenu-mo wipe, awon omo ogun eleto
aabo ti wa ni sepe lati fimu iru awon olufehonuhan bee danrin.
Aare Mugabe so pe, awon omo ogun eleeto aabo yoo
dana ya eni-keni ti o ba fa rogbodiyan ti o fara-pe iru isele ti
o waye ni orile-ede Kenya, ni eyi ti awon eniyan ti o le ni
egberun kan ti padanu emi won, leyin ti egbe oselu alatako fi
ehonu-won ha lori esi idibo ti o waye ninu osu kejila odun 2007.