Ajo isokan
awon orile-ede agbaye UN, so pe, won yoo dari-ji awon ti won
lowo ninu laasigbo ti o waye ni orile-ede Kenya latari esi ibo
orile-ede Kenya lalai fi iya je won gege bi o se ye.
Ninu
abajade kan ti o jade ni ojo-ru Wednesday, awon osise ajo UN ro
orile-ede Kenya lati sejo awon ti won le eto ominira loju –mole
ni asiko paapaa awon olopaa ti won lo lati fe oro naa loju.
Abajade
naa so pe, o daju- saka pe opo awon olopaa ni o wa nidii
laasigbo naa papaa nipa fifi ibon pa eniyan ni-ipakupa latari
aawo ibo naa.
Olori egbe
oselu alatako lorile-ede Kenya, ogbeni Raila Odiga ati Aare
Orile-ede naa Aare Mwai Kibaki ni won fi mule pe awon jewe
olubori ninu eto idibo aare ti o waye ni ojo ketadinloogun osu
kejila odun to koja, eyi ti o sokunfa laasigbo oloselu pupo.
O le
igba(200) eniyan ti won ba laasigbo naa lo, eyi ti o tun bi
lasigbo eleyameya ati oro ojusaaju ninu eto oro-aje sile.