Akowe agba
fun ajo isokan orile-ede Agbaye, Ban-ki-Moon ti ro awon
orile-ede lagbaye lati fi ipile alaafia lele lorile-ede Somalia
nipa sise atileyin eto oselu ti ajo UN n gbe se, ki won si ko
akotun awon omo ogun ti iye won je egberun mejo(8) wa lati
olokan-o-jokan orile-ede.
O so pe
eleyi yoo faaye gba akokuro awon omo ogun orile-ede Ethiopia ti
won seranwo fun orile-ede Somalia lati koju egbe elesin Islam
kan ninu osu kejila odun 2006 ati bi o se le se-e-se lati ko
awon omo ogun apetusawon ti iye won to egberun metadinlogbon(27)
ati awon olopaa egberun-kan ati eedegbeta(1,500) wa si orile-ede
naa.
Ninu ijabo
Olojo-pipe-kan lati fun igbimo alaabo, ogbeni Ban so pe ajo
isokan orile-ede agbaye n se agbekale orisi eto liana meta kan,
lati faaye-gba ifikun-lukun laarin ijoba fidihe oeil-ede Somalia
ati awon alatako.
Akowe-
agba ajo UN naa so pe erongba eto naa ni lati rii daju aaboti o
peye w anile, paapaa saaju eto adehun kosi-ogun-mo ati fun riro
awon ile-ise ijoba ati eto iranlowo omo eniyan lagbara ati
irapada eto oro-aje.