Egbe omo
ogun olote kan ni ekun Darfur ti bere fu ipade ijiroro alaafia
ojukoju pelu ijoba orile ede Sudan. Eyi ti won so wipe, egbe
omo ogun olote ohun lo ku si ekun naa.
Adari egbe
omo ogun olote Justice and Equality Movement JEM, ogbeni Khali
Ibrahim salaye pe ki akowe agba ajo isokan orile ede agbaye
teleri, ogbeni Kofi Anna je atokun ipade ijiroro alaafia naa,
ati pe, ijiroro adehun naa ko gbodo duro lori ekun Darfur
nikan. Bakan naa ki won soro lori eto awon agbegbe yoku no
orile ede Sudan
Ogbeni
Ibrahim so pe, egbe omo ogun olote naa setan lati kopa ninu
ipade ijiroro naa, eyi ti yoo waye niluu Tripoli ti n se olu ilu
orile ede Libya. Sugbon o nii, o gbodo je ijiroro ojukoju pelu
ijoba orile-ede Sudan.